*IFURA LOOGUN ÀGBÀ* (YORUBA POETRY)

*IFURA LOOGUN ÀGBÀ*

Jòjòló Akéwì jí sáyé, mo fi ògo fún Ọlọ́run Ọba

Odomode Akéwì jí sáyé, mo yin Eledumare

Ẹ kú Ojúmọ́ ẹyin ènìyàn mi

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi, mo ti wà lórí idobale

Bí mo bá ti jí, dandan ni ki n ki eégún ilé

Bí mo bá ti jí, dandan ni ki n ki òrìṣà ọjà

Mo júbà gbogbo eyin ajunilo

Jòjòló Akéwì fẹ́ pàṣamọ̀ ọ̀rọ̀

Páńṣá kò fura, Páńṣá já sina

Àjà kò fura, Àjà jin

Bonile kò fura, olè ni yóò jí i gbé lọ

IFURA LOOGUN ÀGBÀ

Taa ló kọ́ ẹ logbon tí kò fi agọ̀ kún un

Ó yẹ kó o fura, kí o wo sakun ọ̀rọ̀

Jòjòló Akéwì kii pàátó ẹnu lásán

Ó ní òhun tí mo rí tó fẹ́ jẹ́ kí n ṣe ẹ loore ẹnu

Ọrẹ mi, farabale koo gbọ́ àlàyé ọ̀rọ̀

Bí ayé bá ń pọn ọ lé, nise lo yẹ koo máa fura

Bí ayé bá ń tẹle ọ lẹyin, ó yẹ koo máa ronú wo

Ọmọ aráyé burú, mo júbà ọmọ adarihunrin

Àwọn ènìyàn ní ń bẹ nídìí eto ìkà

Jiji tí mo jí, orin Ifá ló wá sí mi lẹ́nu

Mo yẹ ifá wò, Orunmila sì bá mi sọ̀rọ̀

Ifá sọ̀rọ̀ ilẹ̀ kún

Ojú odù *Òdí Méjì*  ni ifá fi sọ̀rọ̀

Ẹ jẹ́ kí n ki díè fún yín ọjọ ń lọ

Bí ń ko bá wí, ó lè dà bí ẹsẹ

 *Ilé ni mo jókòó sí*

 *Ire ń wọ tuuru wá bá mi*

 *Ọ̀dẹ̀dẹ̀ ni mo jókòó kà*

 *Ọ̀rọ̀ ń wá tuuru wá bá mi*

 *Mo jókòó àìnàró*

 *Mo rí ire ọrọ̀ tó pọ̀ rẹgẹdẹ*

 *A dia fún Òdí*

 *Lọ́jọ́ tó ń sawo lọ òde Òkò*

 *Ó jókòó, ó fi ẹyin ti igi akòkò*

 *Ire gbogbo ń dà wá o*

 *Igìrìrì Igìrìrì*

 *Ibi a bá fi iyọ̀ sí ni iyọ̀ ń somi sí*

 *Ire gbogbo dà wá o*

 *Igìrìrì Igìrìrì*

 *Òkè kii yẹ tí fi í gbẹbọ tìrẹ*

Ǹjẹ́ ẹ jẹ́ mọ pé ọ̀ràn tó ń dun babaláwo ló ń dun ifá

Ọ̀ràn tó ń dun oníṣègùn ló ń dun osanyin

Ọ̀ràn tó ń dun àjẹ́ ló ń dun oṣó ìdí rẹ̀

Ó jẹ ki n rántí Onídẹlójú tí kò fura

Onídẹlójú ọmọ Orunmila kò fura lọ́jọ́ tó fẹ́ gbàpèrè

Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú odù ifá yẹn, ilẹ̀ máa kún

Jòjòló Akéwì kò fẹ́ gbà yín lásìkò

Ọrẹ mi máa fura

Ọrẹ mi, máa ronú jinle

Alakan kò fura nijosi, ayé da àgọ́ ara rẹ rú

Àgùntàn kò fura, ìyẹn ni kò jẹ kó ni ìwo

Aifura pepeye ni kò jẹ́ kó la ẹsẹ̀

Baye bá ń tì ọ, nise ni kí o má ti ara rẹ

Ayé le, ènìyàn wà

Jòjòló Akéwì ti kọ ọgbọ́n lórí ọmọ aráyé

Ọmọ Saanuade ti kẹ́kọ̀ọ́ lórí ìwà àwọn ènìyàn

Ojú rí, ẹnu kọ sísọ

Fura, IFURA LOOGUN ÀGBÀ


 *JÒJÒLÓ AKÉWÌ*

Comments

Popular posts from this blog

ALAAFIN OF OYO IS 48YRS ON THE THRONE